Káràkátà

Mo ya àwòrán yìí ní ọdún 2020 nígbàtí àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 gbòde kan. Ìyàlẹ́nu ló jẹ fún mí nígbà tí mo ri ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n ń wó bìtìbìtì lọ àti bọ̀ fún káràkátà. Èyí tí o fi lọlẹ̀ pé, òun jíjẹ àti òwò ṣíṣe kò lè dá àwọn ènìyàn dúró kó dà kí àrùn náà le koko.
Márúwá

Àwòrán yìí jẹ lára àwọn ọ̀pọ̀ àwórán tí mo yà nínú ọkọ ẹlẹ́sẹ̀ mẹta, Márúwá èyí tí ìrìn won máa n yà mí lẹ́nu nígbà kúgbà
Nípa Ayàwòrán
Awósùsì Olúwábùkúnmi Abraham jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pẹ̀lú pẹ̀lú, ó tún jé ònko Apilẹ̀kó, Ewì àti Ayàwòrán pẹlú ẹ̀rọ kọ̀mpútà. Àwọn iṣẹ́ rẹ sí tí jáde lórí ayélujára lórísirísi.