Ó kúkú ti pẹ́ tí Náírà ti ń gbọ́ nípa Kọ́bọ̀. Kódà ìtàn sọ fun u pé gẹ́lẹ́ tí Náírà gbòde şóun ni Kọ́bọ̀ doun àkàntì, táyé kò ná mọ, léyì tó fi f’igbó şe ilé.
Ó şe ni ọjọ́ kan, Náírà gbéra ó di igbó, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní wá Kọ́bọ̀ kiri. Ó dààmú púpọ̀, şùgbọ́n ó pàpà ri i. Ó bá Kọ́bọ̀ níbi tó gbé ń yan òkèté níwájú ilé dídára kan. Náírà nahùn pe Kọ́bọ̀, kọ́bọ̀ dáhùn, Náírà sì tọ̀ ọ́ lọ.

Kọ́bọ̀: Náíra,̀ ìwọ ni, ètí şe, kí lò ń wá nínú igbó?
Náírà: Kọ́bọ̀, ìwọ gan ló gbé mi dé ibí.
Kọ́bọ̀: Èmi ẹ̀wẹ̀! Kò şòro?
Náírà: Kó sì ǹkan àti ǹkan ni wọ́n n ́jọ ń rìn
(Náírà gbọn ara rẹ̀ tó kún fún ìdọ̀tí àti ewé kítikìti ó wo àgbègbè rẹ̀ yíká)
Náírà: Kọ́bọ̀ èéşe tí o fi igbó şe ilé?
Kọ́bọ̀: Şe tí wọ̀n kò bá fẹ́ ní nílu, ènìyàn a ma dárin bi? şebí kólúwarẹ̀ kó ara rẹ lọ ibi tí wọ́n á ti gba tẹni ni.
Náírá: Şé igbó ló wá gba tìrẹ?
Kọ́bọ̀: Ẹni gbogbo ló ni igbó ta wà yí.
Náírà: Şèbí igbó fún ẹranko bíburú ni, àti oríşi-ríşi abàmì ẹ̀dá?
Kọ́bọ̀: Ẹ wo Kọ́bọ̀ yìí (ó yíjú), ènìyàn pàápàá ń gbé ibí yìí. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Tọ́rọ́ àti Sísìn ń bẹ níbí?
Náírà: Tọ́rọ̀ ayé ijọ́un!
Kọ́bọ̀: Ẹhn!
Náírà: Ah!
Kọ́bọ̀: Kódà onírú ẹ̀dá ló wà níbí. Ayé wa dùn nínú igbó yìí. Lótìtọ́ kò şe fi wé tìlú, şùgbọ́n ìlú tárìnrìn àjò ń parí àjò sí lawà yìí.
Kọ́bọ̀: Ilé owó ẹyọ ló wà lọ́kànkán yẹn (Kọ́bọ̀ na ọwọ́ sí ọ̀kánkán sí ilé dídára)
Náírà: Kò mà rí bí mo şe ro. Pẹ̀lú igbó kitikiti yìí, mo rò pé inú ìşẹ́ gidi ni ìwọ àti àwọn àkàntì ìlú wa. Kàkà bẹ́ẹ̀ fàáji gidi lẹ wà.
Kọ́bọ̀: Şé o ri Náírà, oníkálùkù ẹ̀dá ló ní àsìkò tí adẹ́dà fun. Bẹ́ẹ̀ işẹ́ tí adẹ́dà pín lé wa lọ́wọ́ şọ̀tọ̀tọ̀, ó sì fi àkókò le láti şe. Bí eré ìje lórí tí oníkálùkù ní àsìkò láti sátìrẹ̀, asáraparì tirẹ̀, ẹlòmiràn a sì gbà á. Ìgbà èmi Kọ́bọ̀ sá, àkókò tó ìwọ Náírà gbà a. Eré ìje ni ìwọ ń sá lọ́wọ́.
Náírà: Ó yémi báyìí (Ó mi orí). Ó sì wùn mí ki n rí Tọ́rọ́ àti sísì o. Ǹjẹ́ mo lè ma gbé ibí, Igbó yìí wùn mi?
Kọ́bọ̀: Tọ́rọ́ àti Sísì şọdẹ lọ. O kò sì lè gbé ibí, Igbó ìsinmi nìyíì. Ìwọ Náírà kò tí lo ìgbà rẹ tán. Nítorí náà, o kò lè̀ dúró púpọ̀ níbí pàápàá, kí ìpalára má ba wà fún ajé àti ohun pàtàkì ní ìlú. Ipò ńlá ni ìwọ Náírà dì mú láwùjọ. Jẹ́ işẹ́ rẹ tán kí o tó gba ìsinmi. Şe ko wá ma lọ. O kú àbẹ̀wò mi.
Náírà: O şeun Kọ́bọ̀ fún àlàyè rẹ. Bámi kí Tọ́rọ́ àti àwọn tó kùn. Ó dìgbà!
(Náírà jáde lọ kúrò nínú igbó, Kọ́bọ̀ pa lẹ́sẹ̀ da).


Foláşadé ọmọ Oláòníye jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìdèrè ní Ìbàràpá. Ó parí ní ilé ìwé gíga fáfitì Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀ ní ilé-ifẹ̀. O jẹ́ akẹ́kọ̀ gboyè ìmọ̀ òfin. Ó fẹ́ràn láti máa ka ìtàn Yorùba àti láti máa sọ ìtàn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó kúndùn àwọn ìwé àgbà òǹkọ̀wé tó ti sùn ùn nì, D.O Fagunwa, kò le fiwọ́n şeré rárá. Ó fẹ́ràn Yòrùbá lọ́pọ̀lọpọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *