Gbogbo rògbòdìyàn tó ń lọ ní’gboro tojú sú ni pátápátá.
Tí t’ arúgbó t’omidan fi ń sá hílà-hílo
Tí ìbẹ̀rù ìṣẹ́ òhun òṣì fi ń mú t’ẹru t’ọmọ wayín keke.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ jáde wọn ò ríṣẹ́
Ń ṣe ní wọ́n ń f’ojoojúmí wá’ṣẹ́ kiri bí bí orí tí wọ́n sá-ń-gi.

Baálé ilé di ẹbí ọlọ́kadá ká le rọ́wọ́ mú b’ ọnu.
Ọmọ ò gbọ́ràn sí bàbá lẹ́nu nítorí kò sí ṣílè lápò.
Wọn a wọ́ṣèé lé Ìyálé ilé nítorí oúnjẹ. Ìjọba ò ráyè léṣè wọ̀gbẹ́ mọ́
Oun tí kálukú fẹ́ẹ́ jẹ ni wọ́n ń wá kiri
Ìjọba àwa-ara-wa ti wá di ìjọba àwọn-ara-wọn

Kọ̀ǹgílá pàápàá ò ráyè iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún-un
Owó ìlú ni gbogbo wọn fi ń ṣara rìndìn.
Ilé ìgbafẹ́ ni ọ́fíìsì ìjọba lóde òní
Àwọn àlè ò jẹ́ kí wọ́n gbádùn ìṣẹ́ òhun mọ́.
Olóṣó ni wọ́n ń fi ojoojúmọ́ gbé kiri.

Àti Gómìnà àti Aláṣẹ ìlú ọdún káyó-káyó ni gbogbo wọn ń fi ojoojúmọ́ ṣe.
Kówó pé ni gbogbo wọn ń bá kiri.
Kò kàn wọ́n bí mẹ̀kúnù bá sọ ìṣẹ́ òhun òṣì di fújà tí wọ́n ń wọ̀ s’ọ́rùn
Bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ ò fẹ́ẹ́ gbà lẹ́rọ̀ mọ́
Tí àwọn gídìgáńkú fi ń wá owó òjijì kiri.

Ilé ìfowópamọ́ ni wọ́n tún ń jà lólè
Àbí kíni ká tí gbọ́ pé ọmọ dá ẹ̀mí bàbá ẹ̀ lègbodò nítorí owó
Kín-ín-ni ká ti pe ti màjẹ̀sín tó rán bàbá ẹ̀ s’álákeji nítorí owó ìfẹ̀yìntì.
Àwọn aṣojú-ṣ’òfin tí a tún fi’ṣẹ́ rán ń kọ́ nílé ìgbìmọ̀ aṣọ̀fin ń kọ́?
Ìṣẹ́ ara wọn ní wọ́n ń f’ojojúmọ́ jẹ́ kiri.
Wọn ò kúkú rántí àwọn tó yàn wọ̀n sípò.

Bẹ́ẹ̀ làwọn adájọ́ ń lo’dà òfin bó ṣe wù wọ́n
Tí wọ́n ń dájọ́ taa ni yóò mú mi.
Rìbá ti jẹ́ kí wọ́n gb’ẹ́bi fún aláre
Tí aláìmọ̀kan ń f’ẹ̀wọ̀n lògbà.
‘Òtu ti ń ṣẹ̀wọ̀n raré’ ni wọ́n ń sọ kiri.

Àwọn agbófinró pàápàá ń tẹ òfin lójú fúnra wọn.
Wọ́n a tẹ’lẹ̀ ṣùà-ṣùà bí ẹni pé s’Olúwa ọba
Orin ta ló fẹ́ẹ́ mú mi wọ́n kọ kiri.
Ṣùgbọ́n ikú tí yóò pa oníkálukú ń mì bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ lọ́run kówá wa.
K’Èdùmàrè má jẹ́ ká f’òṣì lògbà.

Ìṣẹ́ ò dára fún ọmọlúàbí
Òṣì ò yẹ ọmọ ènìyàn
Òṣì níí yọ fújà lẹ́gbẹ́
Òun náà níí yọ ènìyàn láwùjọ olóríire
Kí Èdùmàrè má f’òṣì ta gbogbo wa.

Nípa Òǹkọ̀wé

Núrénì Àrẹ̀mú Bakẹnnẹ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta. Ó jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Táí Ṣólàríń tó wà ní ìlú Ìjẹ̀bú Òde, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó gboyè Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ga jù lọ (Ph.D.) nínú Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì Ìkànsiraẹni (Communication Sciences) ni Fásítì North-West tó wà lórílẹ̀ èdè South Africa, níbi tó ti bojú wo ipa tí BBC Yorùbá ń kó nínú ìdápadà èdè, àṣà àti ìṣe Yorùbá ni Gúúsù Ìwọ̀-Oòrùn Naijiria. Ó jẹ́ ògbóǹkangí akọ̀ròyìn àti akaròyìn lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ló tún jẹ́ ògbufọ̀. Onírúurú iṣẹ́ ìwádìí ló ti ṣe lórí iṣẹ́ tó yàn láàyò, bẹ́ẹ̀ ìrírí rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti tó ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, ó ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí nílé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Ghent ní orílẹ̀-èdè Belgium. Ìṣẹ́ ìwádìí yìí níí ṣe pẹ̀lú àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ tí wọ́n tẹ̀ jáde lédè Yorùbá. Ní pàtàkì jùlọ, ó ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí ìwé ìròyìn àkọ́kọ́ tí a tẹ̀ jáde ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà – Ìwé Ìròhìn Fún Àwọn Ará Ẹ̀gbá àti Yorùbá. Láìpẹ́ yìí ni wọ́n yà ń gẹ́gẹ́ bíi aṣojú orílẹ̀ èdè Belgium nínú àjọ kan tó ń ṣe ìgbélárugẹ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ (E-COST).

Àwòrán ojú ewé láti ọwọ́ọ Meta AI

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *