Ìfarajìn

Fún D

Eléyìí le wá sópin ní àwọn ọ̀nà méjì

Pẹ̀lú rẹ, Mo fẹ́ èyí tó dára –
Níbi tó jẹ́ pé a ti ń padà sọ́dọ̀ ara wa ní gbogbo ìgbà.

tí à ń fi nǹkan tí kò kùnà láti máa bà wá jẹ́ sẹ́yìn,
tó ń mú wá ní àìmọ̀lárá láwẹ́ láwẹ́ débi tí nǹkan kan ò kọrin.

Rárá, kì í ṣe pé a ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro ayé,
tàbí a tọ́jú ara wa pamọ́ nígbà tí òkùnkùn ayé dé.
Torí pé ìyẹn náà máa wá wa rí, gbogbo àwọn ìjàmbá kéékèèké,
Bí wọn ṣe gọ pamọ́ deni, àtipé nígbà tí wọ́n bá ṣọsẹ́,
Bí wọ́n ṣe mi ayé wa tìtì, a máa mú inú wa ru fùfù
kí á sì ṣòfo ìrètí bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ọjọ́, ìdánìkanwà ju bí ó ṣe yẹ lọ,
Kódà nígbà tí a bá wà pẹ̀lú ara wa.

Ohun tí mo fẹ́ ni àmọ̀dájú wá,
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwárìrì tí ó là gba inú ìlẹ̀,
Pẹ̀lú gbogbo àníṣẹ́kù àti àwọn ọdùn ìdánìkàngbé,
Pẹ̀lú gbogbo ohun tí a dáàbò bò àti ohun tí a pàdánù,
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìyípadà: ìlera mi tó ń dínkù,
Sùúrù tìrẹ tó ń yọ́, ìkorò mi, ìbànújẹ̀ rẹ.
Gbogbo àwọn ọjọ́ wa, à ń ní ìgbọ̀nmọ̀ kinní aláìkóradúró ìmọ̀sílára yìí
Tó ń lóokè lọọlẹ̀ bíi ìgbì – tó ń bórí
Pẹ̀lú àìdùrógbári ni àwọn ọ̀nà rẹ̀. A gbé èmi alágídí rẹ̀ wọ̀ sínú wá,
A bá a jà, ṣùgbọ́n a sáábà má ń kúnà torí pé ó ti borí ọkàn wa,
èmí wa, pẹ̀lú ìfẹ́ ara wa sira wa.

Síbẹ̀, nínú gbogbo èyí, ìdánilójú wa ní ó ṣẹ́kù,

Èyí tó jẹ́ pé kódà nísinsìnyí, nígbà tí ó ti sọdá tí
Mí ò sì le fara dà ẹ́ mọ́, mí ó lè fara da irú ìfarajìn yìí,

Nígbà tí mo fẹ́ ṣe ẹ́ ní ṣùtá pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu mi tàbí gbẹ́ kòtò
Ìdákẹ́jẹ́ sáàárín wa, mi ò gbé ọwọ́ mi nígbà tí o
fẹ́ mú un. Mo fi pamọ́ síbẹ̀ bákan náà, lábẹ́ ìmóóru àtẹ́lẹwọ rẹ,
àwọn ẹ̀gbọ̀rìrì jẹ́ẹ́jẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í súyọ. Báyìí ni mo ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ:
Nígbà tí gbogbo ohun tí ń bẹ nínú mi fẹ́ tutù kí wọ́n sì jìnnà,
Mo tẹ orí mi ba mo sì gbin ìfẹnukonu kan sẹ́yìn ọwọ́ tó le koko.

Nípa Òǹkọ̀wé

Tryphena Yeboah jẹ́ òǹkọ̀wé orílẹ̀-èdè Gánà tí ó kọ́ àkọ́jọpọ̀ ewì, A Mouthful of Home (Akashic, 2020), tí ó wà nínú New Generation African Poet Series. Ìtàn àròsọ rẹ̀ àti àpilẹ̀kọ rẹ̀ tí fara hàn nínú Narrative Magazine, Commonwealth Writers, àti Lit Hub, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ní Fásítì Nebraska-Lincoln, tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú ìtẹpẹlẹmọ́ ìmọ̀ Ìkọ̀wé Alátinúdá.

Read original work on Agbowo.

Cover Picture by Meta AI

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *