Apá Kiní
Emọ́ kú ojú òpó dí
Eésùn là, o là dànù
Ọ̀pálánbá ọtí èèbó fọ́
Onígbá sọọ́ kò ri sọ
Ta ń mọ bi ọgbọ́n tún ń gbé?
Ta ń mọbi òye kù sí?
Ifálétí ọmọ Àkànbí
Ikú pa gbe, ó paró
Ikú pàlùkọ̀, ó posùn
Ikú pọmọ Fálétí òun Ìṣòlá
Ó pa gbogbo ọlọ́gbọ́n ayé mọ
Àràbà baba Lápàdé
Awo Tàfá,èèyàn Súlè
Àyímọ́ kìí pọlọ́kọ̀.
Níjọ́ Adébáyọ̀ kú
Níjọ́ Fálétí fi wá sílẹ̀
Tó rọ̀run, igí dá ni
Odó kò le è ró póró
Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ wọn ò le gbọnra wú
kẹ́wúkẹ́
Màjèsín inú ilé kò le è sunkún ọmú
Níjọ́ Òkédìjí rọ̀run
Igbá ilé wọn ò le lura wọn
Olùkọ́ àwọn àgbà olùkọ́
Odò ìmò tí gbogbo ọ̀mọ̀wé ń pọn
Ọmọ ìṣọ̀lá akọ́nimákùsíbìkan.
Níjọ́ tọ́ ní ọmọ Fálétí kú
Mo ní irọ́ ni,
Mo ní ikú kí ní ń pagbe
tólóko kìí gbọ́ nílé
Mo ní ikú kí ní ń pàlùkò
tọ́lọ́sà kìí gbọ́dẹ̀dẹ̀ mọ̀
Mo ní kú kíní p'ọmọ Àkànbí ẹ wí fúnmi
Pagidarì igí dá.

Apá Kejì
Ìyá tó báṣọló bẹ́wùló bí sòkòtòIgi àràbà mẹta ló papọ̀dàL'éwì, l'éré oníṣe, nítàn àròsọỌmọ ìyá ni wọ́nỌládẹ̀jọ Ọ̀kédìjìOnítàn àròsọ olẹ́tẹlẹ̀múyẹ́Awo Lápàdé, èyan TàfáAkínwùnmí Ìṣọ̀láBaba ìyálódeỌkọ Ẹfúnṣetán
AníwúràAdébáyọ̀ FálétíAwo Adébíḿpé Ọ̀jẹ́dòkunÈyàn sáṣore ọ̀rẹ́ àtàtàÌyá tó báṣọló bẹ́wùló bí sòkòtòẸ má yà wọ́nẸ má yà wọ́n
Láti ọwọ́ Omidan Kọ́dáolú Tolúlọpẹ́ (Apálará).Akẹ́kọ̀ọ́ àti Olùkọ́ èdè Yorùbá ni Ifásitì Ìbàdán.