Igúnnugún bà lórùlé
Ojú kálé,
Ojú káko.
Òrí akéwì kò ní jábọ́
Kó má yí nǹkan.
Kí láǹfààní orógbó?
A pa á, kò láwẹ́
A jẹ́, ó tún korò bí i jogbo
A tún ní ká figi rẹ̀ dáná
Ó kọ̀ kò tún jó.
Kí ni lááríjà ìjọba alágbádá ?
Èwo láǹfààní òṣèlú alálùpàyídà?
Ẹ ń pariwo ọ̀dájú nìjọba onikakí
Ẹ ń kébòsí afẹ̀tọ́-ẹnì-dunni ni sọ́jà
Olóṣèlú fọgbọ́n àrékérekè lé wọn sí bárékè.
Wọ́n ń ṣèlérí pé alágbádá
Ló le sọ̀rọ̀ ilẹ̀ yìí dẹ̀rọ̀
Wọ́n fẹnu yaran sọ́bẹ̀
Wọ́n bọ́ sórí àlééfà.
Ni wọ́n bá sọ ìpàkọ́ sẹ́yìn.
Ìwà kò ní foníwà sílẹ̀.
Báwo là ó ṣe ṣe ebòlò
Tí kò ní rùngbẹ́?
Bó o là ó ṣata
Tí kò ní gbé ìṣe rẹ̀ yọ?
Wọ́n dórí àpèrè tán
Wọ́n ń lu owó ìlú ní póńpó
Bí wọ́n ti ń ko ó pamọ́ sílé
Náà ni ti báǹkì ò lóǹkà
Tòkè òkun gan-an ò gbẹ́yìn.
Wọ́n kọjú mẹ̀kùnnú sóòrùn alẹ́
Wọ́n ń jayé e fà-mí-létè-n-tutọ́
Ìyà àjẹkúdorógbó ń pa wọn lórí
Eku káká ni wọ́n fi ń roúnjẹ jẹ
Tipátipá lọmọ fi ń re sùkúù.
Àwọn kan náà lòṣẹ̀bọ kẹ́bọ jẹ.
Bí wọ́n ṣètò tí yóò wúlò fáráàlú
Ìwọ̀nba èèyàn ni ó jàǹfààní ẹ̀
Àwọn olóṣèlú ní yóò da ìyókù sápò.
Kò sóhun tí wọ́n ṣe fáráàlú tó kẹ́sẹ́ járí.
Wọ́n ń fohun àjọni lá wa lójú
Bí wọ́n fẹ́ gbani síṣẹ́
Arúmọjẹ lásán nìkéde orí i rédíò
Irọ́ lásán ni torí tẹlifíṣàn.
Àwọn tiwọn ni ó padà rí iṣẹ́ ọ̀hún.
Ọlọ́run ni n ṣèdájọ́ afeyín pínran
Bí wọ́n bá ń fẹ́ dìbò
Ilé e mẹ̀kúnnù kì í jìnnà
Wọn a fẹ́rẹ̀ tẹmọ adìẹ pa
Wọn a máa ṣèlérí asán.
Bí wọ́n bá fẹ́ gbààwìn
Ojú àánú wọn kò láfiwé
Bí wọ́n bá ti yó tán
Ọkọ olóúnjẹ ni wọn ó dà.
Bí wọ́n bá ti bódìí sílé ìjọba
Àlọ wọn a di ti lámilámi.
Mẹ̀kúnnù ò bèèrè ohun tó pọ̀
Bóhun amáyédẹ̀rùn bí omi,
ọ̀nà, èto ẹ̀kọ́, iléeṣẹ́, iléewòsàn,
iná ọba, ìpèsè iṣẹ́, ètò ààbò
Bá ti dúró wámúwámú.
Àbùṣe kúkú ti bù ṣe.
Wọn ò pèsè àwọn wọ̀nyí
Ara ni wọ́n fi ń ni mẹ̀kúnnù
Àti róúnjẹ jẹ di wàhálà
Ọ̀pọ̀ tó ń rìn ti kú sógúròdo.
Ọmọ mẹ̀kúnnù tó kàwé ò ríṣẹ́
Ẹ dákun ẹ ṣàánú mẹ̀kúnnù!
Ọrọ̀ ilẹ̀ yìí kúkú tó ó pín
Báwọn olórí ò bá ya bóorán.
Tí wọn ò hùwà ànìkanjọpọ́n.
Nípa Òǹkọ̀wé
Ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ lórí ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́.