ÀKỌ́LÉ :Orí
OHUN ÈLÒ: Ọ̀dà Ọìlì
ỌDÚN : 2014/2015
ORÚKỌ AYÀWÒRÁN: Ọláòníye Àllíù Fèyíṣọlá
GBÓLÓHÙN IṢẸ́ NÁÀ– Òrìṣà pàtàkì ni a mọ orí sí láàrín ọkanlélúgba irúnmọlẹ̀, bẹẹni kò sì ṣé f’ọwọ́ rọ́tì sẹ́yìn rárá nínú iṣẹ ọnà. Àkọ́kọ́ níbẹ̀ ni ṣíṣe àwòrán rékété, ọ̀pọ̀lọpọ̀ fọ́ọ́mù bi ọfali, konu, gbogbo rẹ̀ lójẹ́ ìpìlẹ̀ fún iṣẹ́ ọnà. Fífi pátánì sí iṣẹ́ ọnà dára púpọ̀. Àwọn àwòrán naa ni ìjàpá, ọ̀gà, adé, ẹja, ife, ilẹ̀, àti ìlarun. Gbogbo nnkan wọ̀nyìí lóni ìbátan pẹ̀lú Orí bíbọ.
ÈRÒJÀ IṢẸ́ NAA: Búrọ́sì, aṣọ funfun, gọ́mù, akiriki, àti bẹ́ẹ̀bẹẹ̀ lo.
ÀKỌ́LÉ :Àdìrẹ Oníkòó
ỌDÚN: 2018
ORÚKỌ AYÀWÒRÁN: Ọláòníye Àllíù Fèyíṣọlá
SÍTÁILÌ: Aṣọ Àdirẹ.
GBOLOHUN ISE NAA -Aṣọ wíwọ̀ jẹ́ ohun pàtàkì nílẹ̀ Yorùbá. Oriṣiríṣi aṣọ ni ó wà bí gbáríyẹ̀ẹ́, bùbá. Eléyìí jẹ́ àwọn aṣọ ìdánimọ̀ gẹ́gẹ́ bi ọmọ Yorùbá pọ́nbélé. Nípa iṣẹ́ ọnà (artistic work)tie ati re jẹ aṣọ amúlùmálà tí ó tóbi jù púpọ̀. Ama ń fi aró ṣe iṣẹ naa daradara bi apẹẹrẹ -Aró aláwọ̀ pupa, Aláwọ̀ dúdú, Aláwọ̀ ewé àti bẹẹbẹẹ lọ. Gẹgẹ bi aṣọ àdirẹ ṣe jẹ́ ojúlówó Aṣọ Yorùbá. O sì tún jẹ́ ohun pàtàkì tí a maa ń fi ọwọ ṣe pẹ̀lú ohun èlò naa o gbẹ́yìn níbẹ̀. Orúkọ ti o tumo si naa ni Adìrẹ oníwaro àti òṣùpá (stars and moonlight).
Ọláòníye Àllíù Fèyíṣọlá jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yorùbá. Abi sí ilu Igbóọràkan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ijọba ìbílẹ̀ ìbàràpá. Ó ṣetán ní fáfitì Ifẹ̀ (Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀ University) ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun. Iṣẹ́ ayàwòrán ni ó yàn láàyò, bi iṣẹ́ ọnà (embroidery/craftwork), Àwòrán (portrait) àti pípa aṣọ láró (táì, dáì àti bàtíkì). Gbogbo rẹ̀ lóni ìbátan lórí iṣẹ́ ayàwòrán. Ẹ kàn si Fèyí ni orí ago +234 705 827 3046.
Atelewo Yoruba Language Art Literature Adire cloth culture Poetry Arts Egbe Atelewo Atelewo Nigeria Yoruba Read Iwe Yoruba Ise asa Atelewo