Adé-ìmọ́lẹ̀ náà wúwo lórí ẹni mímọ́ náà,

Ó rúnjúpọ̀ fún àpọ̀jù-ìmọ́lẹ̀
tó wọ̀ ọ́ lójú, ó ti kó ṣáwùjọ̀ aláìrọ́runwọ̀.

a gbe dè sórí àpèré,
Òrìṣà náà ń ṣèdájọ́ aláìnígbèdéke.

A tá a lọ́rẹ ìṣẹ̀mí gbere,
Dá a lẹ́bi láti jí kalẹ̀
– Ojú mùjẹ̀mùjẹ̀ náà tí di pirimù fẹ́jẹ̀.

Ó lo ipò kánrin – Ọba
ère náà – wọ́n tẹrí ba fún ẹni tó mú
àwọn ọwọ́ tí a dè jáde títí láéláé.

Nípa Òǹkọ̀wé

Funmi Gaji gboyè Ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde àkọ́kọ́ rẹ̀ nínú Ìmọ̀ Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni Fásítì Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó tẹ̀ síwájú láti gboyè ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ni Fásítì Ìbàdàn. Ó jẹ́ òǹkọ̀wé The Script of Bruises. Olùwádìí àti olóòtú, àwọn ewì Gaji ti fara hàn nínú ÀNÁ Review, Jalada, àti ní àwọn ààyè mìíràn. Wọ́n ṣàkójọ́ iṣẹ́ rẹ̀ nínú Unbound: Àkójọpọ̀ tí New Nigerian Poets Under 40.

Cover Image by Meta AI

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *