Àwọn ènìyàn ìlú mi ń
lá àwọn ìka wọ̀bìà wọ́n mọ́
níbi ẹ̀jẹ̀ tó ń tọ jáde
pẹ̀lú ìgbàgbé pé ìka àárín
ń padà tọ́ka sí wọ́n.
À ń sòkúta mọ́ ilé aláwo àwọn kan
Bíi àwọn ọmọ àlè tó gbàgbé pé
òkúta á máa ta padà wá sẹ́yìn
ba ẹni tó jù ú.
A yan àwọn olórí nítorí
T’ẹ̀yà & kì í ṣe t’ọgbọ́n
Tó wà nínú ọkàn wọn. Ìtọ̀jú borí
Ìṣúra ní àjogúnbá ti wa.
A pa irọ́,
À ń mọ ebè ẹ̀bi
Lórí àwọn ebè sí àwọn ebè
& nígbà tí ìbọn náà bá tìdí jò,
Nígbà tí dígí bá san
& tó fọ́ sí àwọn ẹ̀rún aláìláforíjìn,
Àwọn àfọ́kù náà, tó ń fọ́nka kiri
Ayé wa, tó ń ṣe wá lọ́ṣẹ́ –
À ń lo ìṣẹ̀mí lọ, nínú rúgúdù náà.
Nípa Òǹkọ̀wé
Rahma O. Jimoh jẹ́ òǹkọ̀wé alátinúdá àti akọ̀ròyìn. Ó jẹ́ ọ̀mọ̀wé Hues Foundation ti ọdún 2021 ó sì tún jẹ́ Òlùfàkalẹ̀ Pushcart Prize ti ọdún 2020. Olólùfẹ́ ìwọ̀sùn-òòrùn àti àwọn ohun mèremère. Iṣẹ́ rẹ̀ tí jẹ́ gbígbé jáde tàbí ó ń bọ̀ lọ́nà ní Lucent Dreaming, Olongo Africa, Native Skin, Agbowo, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ó jẹ́ àṣàyàn òǹkọ̀wé nínú ìdíje Poetically Written Prose, The Eriata Oribhabor Prize, pẹ̀lú Abubakar Gimba Short Story Prize. Ó jẹ́ olóòtú ewì fún The Quills àti Olúmọ Review. A máa ká ewì ní Chestnut Review.
Read Original work on Brittle Paper.
Cover Image by Meta AI