Àtẹ́lẹwọ́ jẹ́ ìwé àtàtà….
—–Kọ̀ngọ́ Ọ̀rọ̀ (Graduate Assistant, University of Birmingham, Member (Yoruba Studies Association of Nigeria (YSAN), Former Language Instructor, American Council on the Teaching of Foreign)
Àkójọpọ̀ yìí láti ọwọ àwọn òǹkọ̀wé tí wọn wà ni ìpò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú iṣẹ́ wọn, Àtẹ́lẹwọ́ tan ìmọ́lẹ̀ sí ẹwà èdè Yorùbá, ìtàn, àti àṣà rẹ̀. Ní ọwọ́ àwọn akéwì yìí, àwọn ònkàwé ṣe alábàpàdé oríṣiríṣi nǹkan nípa ìfẹ́, ìjẹ́ oníwàrere, gbígbé orílẹ̀ èdè lárugẹ́, ṣíṣe akin nínú iṣẹ́, àti ṣiṣe déédé lara àwọn ǹnkan míràn. Àwọn òǹkàwé yòó kan sárá sí ìwúlò tàbí laarija Yoruba nípa fífi ẹhónú tí o ṣe pàtàkì sí ìrírí ojoojúmọ́ àwọn ọmọ ènìyàn. Àtẹ́lẹwọ́ jẹ́ ìgbìyànjú alágbàtà nípa ìgbìyànjú tòótọ́ láti gbé àṣà ìtàn àrokọ Yorùbá larugẹ.
—Saheed Adérìntọ́ (Western Carolina University, USA)
Lẹ́yìn ti mo ti ka àwọn àkójọpọ̀ wọ̀nyìí, mo gbé òṣùbà fún iṣẹ́ ribiribi tí àwọn òǹkọ̀wé naa ṣe. Ẹwà èdè tí wọn lò nínú àkójọpọ̀ yìí dára gán-an ni, àtipé àwọn òǹkàwé yòó rí bí wọn ṣe tan ìmọ̀lẹ́ sí gbogbo ǹnkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ wa.
—Ààrẹ Ajíbọ́lá Ìshọ̀lá (President, Yoruba Students’ Association (2010-2011), Best contributor to language association, (2008), Adeyemi College of Education, Ondo, and Most active writer of the year (2008).