Ayé yìí ò le Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lejò ń gàgbọn. Ayé yìí ò gba gìrìgìrì Lọ̀gà fi ń tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́jẹ́. Ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ ló láyé Dúníyàn ò fẹ́ gìrìgìrì. Ẹ̀kọ gbígbóná ń fẹ́ sùúrù Ìkánjú kìí gbéni débi kan Àbámọ́ ní ń kẹ́yìn ẹ̀. Bójú bá fara balẹ̀ A kúkú rímú. Ìran ọlọ́gbọ́n a tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́. Ìran òmùgọ̀ a tẹ̀ ẹ́ bàṣùbàṣù. O jẹ́ rọra onímọ́tò yìí Ẹ̀mí kan ma ló ń bẹ Rántí àwọn èrò tó o gbé Bí ìwọ bá ti ṣòògùn àìkú. Àbí tajútajú tó o mu tí ń tọró? Àbí gbáná tó fà ti ń ṣiṣẹ́? Kí làgbọ̀nrín rẹ rí gan-an Tó fi ń ṣekùn gbẹndu sọ́lọ́dẹ? Wọ́n ní kó o dín eré kú Nítorí à súre tete kò le Sáré kọjá ilé. A rìn gbẹ̀rẹ̀gbẹ̀rẹ̀ lọ́nà Kò ní sùn nírònà. Àbí ẹ ti ní òkú èèyàn lọ́rùn Ní dẹ́rẹ́bà ń fọ̀ létè? Ká pẹ́ débi à ń rè Sàn ṣe ká kánjú re kìyáómọ̀. Ẹni tó bá sọ pákéwì ń pàátó Kó relé ìwòsàn lọ wo Àrà táṣídẹ́ǹtì ti fàwọn èèyàn dá Ó ti pẹ́ tí mo ti ń wakọ̀ Kò ràn án rárá ọ̀gá dẹ́rẹ́bà! Àpá kò lè jiná dàbí ara láéláé. Dẹ́rẹ́bà yìí o jẹ́ rọra Rántí pé ẹni tó dárí sílè Òun láwakọ̀ tó dáńgájíá.
Nípa Òǹkọ̀wé
Ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.