Ẹni tó bá mọ àlùmúńtù Ẹ bá mi wá a lọ, a ní gbólóhùn Ẹni tó bá mọ abà tí ikú ń gbé Ẹ bá mi ké sí i pé ìpàdé ń bẹ Ẹni tó bá mọ ọ̀nà tí ikú ń tọ̀ Ẹ sọ fún un pé kò dúró ní ìrònà Ọ̀rọ̀ wà tí a fẹ́ dìjọ yànnànà. Bí ẹ bá ń jáyà láti jíṣẹ́ Kò burú ẹ jẹ́ ń fohùn ránṣẹ́ Sí oníṣe Olódùmarè tó ń Fojoojúmọ́ pa ni lẹ́kún Ẹ jẹ́ ń pàrokò sí àkàndá ẹ̀dá Tí ń fìgbà gbogbo kọ́ mọ́ adáríhunrun nií pápá mọ́ra. Tí ó fọwọ́ lẹ́rán kéèyàn ó ṣebẹ̀ tó dùn létè Tí ó sì yọwọ́ èèyàn nínú oúnjẹ lójijì Lásìkò tó yẹ kó máa jẹ̀gbádùn ọbẹ̀ ọ̀hún. Tí ń dènà dè wọn lọ́nà oko Tí ń dẹ́bùrú ọmọ Ádámọ̀ lọ́nà Tí ń sọmọ aráyé dọmọ òrukàn Tí ń sọ aya di opó láìròtẹ́lẹ̀. A sọ onílé dẹni tí ń sùn ní gbàgede A sì sọ ẹni tó ń sùn lórí tìmùtìmù Dẹni ń sùn nínú erùpẹ̀ A sọ onílé di ọlọ́dẹ àpàpàǹdodo. Ẹ bá mi bèèrè lọ́wọ́ Àlùmúńtù Pé kí ló dé tíkú kìí gbàyọ̀ǹda Kò tó wọlé wá báni lálejò Àlejò tí ò ṣe é lé dànù Àńbèlètè a ń sá á fún. Àlùmúńtù tí já èrò tí kò pè sọ́kọ̀ sílẹ̀. Ẹ bá mi wí fún un pé kó rọra Iṣẹ́ tó ń jẹ́ ó padà wá kàn án bó pẹ́ Ọba mi Yarabi ó gbẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ kan Tí gbogbo wa ó di sàwáwù. Ìgbà yìí lòun náà ó mọ̀ Bí iná tó fi ń jóni ṣe ń rí lára.
Nípa Òǹkọ̀wé
Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.
Àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé jẹ́ ti Cleveland Art
Ikú pin, ó pin
Ikú pin, ó dẹtì
Bíkú bá ń ṣa ẹgbẹ́ mi pa
Ọ̀tọ̀ lọ̀yẹ̀kú yóò máa ṣà mí sí….
Ẹ kú àrògún sà. Ẹ sì kú ohùn.