Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Fi ìtàn sílẹ̀ fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ
Kí wọ́n le máa rántí rẹ nínú ìwé ìtàn.
Gbogbo ohun tí a bá ṣe lónìí, ọ̀rọ̀ ìtàn ni bó dọ̀la
Gbogbo ayé ló máa tán
Gbogbo wa la máa padà dìtàn.
Nítàn kí o tó tan ọ̀rẹ́ mi
Irú ìtàn wo lo fẹ́ ní?
Kí lo fẹ́ káyé sọ nípa rẹ bí tí tán bá dé?
Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Pàtàkì ni ká nítàn
Pàtàkì ni ká fi ìtàn sílẹ̀ sáyé
Káyé le rántí wa nígbà tí tí tán bá dé bá wa
Tí a padà dìtàn fáyé láti kà.
Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Ìtàn wo lo fẹ́ káyé kà nípa rẹ̀ bí o bá tán
Ǹjẹ́ o ń múra sílẹ̀ fún tí tán?
Ìtàn wo lò ń kọ sílẹ̀ fọ́mọráyé?
Nítàn kí o tó tán ọ̀rẹ́ mi
Fi ìtàn sílẹ̀ fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ
Kí wọ́n le máa rántí rẹ nínú ìwé ìtàn
Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ kí n nítàn
Kí n nítàn
Kí n tó tán
Kí ìtàn mi tàn káyé
Nígbà tí mo bá tán.
*Àwòran tí ó wà nínú ewì jẹ́ ti Julian Sinzogan tí ó pè ní "Àwọn Ọba Ilẹ Yorùbá"
Malik Adéníyì (RMA) kọ ewì yìí ránṣẹ́ láti ìlú Ìbàdàn.