Ìdùnnú a ṣubú lu ayọ̀ Lọ́jọ́ a bá bímọ tuntun sáyé Tẹbítará a kí túńfúlù káàbọ̀. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ Tóṣù ń gorí oṣù Ìrètí bàbá ni kọ́mọ ó dàgbà Ìrètí ìyá ni kọ́mọ ó dẹni gíga. Àmọ́ ọmọ kọ̀ kò rá Túńfúlù ìjọ́sí fárí gá kò rìn. Àwọn tí wọn dìjọ dáyé Gbogbo wọn ló ti ń sáré kiri Àwọn tó dìjọ jẹ́ irọ̀ Lòbí ti ń jẹun wọn. Ìyá ń tójú bọlé aláàfáà Bàbá ń fọ̀rọ̀ lọ aládúrà Wọn ò gbẹ́yìn nílé oníṣègùn Nítorí kọ́mọ ó lé dide nàró Ọmọ kọ̀, kò rá kò sì tún rìn. Àsẹ̀yìnwá Àsẹ̀yìnbọ̀ ìgbìyànjú Wọ́n ní kí wọn ó béèrè lọ́wọ́ ìyá Wọn ni kí wọn ó tẹ baba nínú. Torí ọmọ tó kọ̀ tí kò rìn yín Díẹ̀ lọ́wọ́ ìyá díẹ̀ lọ́wọ́ baba. Kò pẹ́ kò jẹ́ jìnà Ọmọ tí a wí bẹ̀rẹ̀ sí í rìn Ọmọ ọ̀hún dàgbà lójú òbí ẹ̀ Ọmọ ọ̀hún pọ́dún méjìlélọ́gọ́ta Kò ì lè dá bùkátà gbọ́ Ọmọ tọ́jọ́ orí rẹ̀ kìí ṣe kèremí Tí ò mọ dàbìdábí Kàyéfì ńlá ló jẹ́ fára àdúgbò. Ọmọ yìí ó le dóhunkóhun ṣe Bọ́mọ ọ̀hún ò bá dọ́dọ̀ ará ilé kejì Kò le rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu lójúmọ́ Ìkòríta mẹ́ta tó ń dààmú àlejò Lọ̀rọ̀ ọmọ kàyéfì tákéwì ń wí. Àwọn olóye lọ̀rọ̀ mi le e yé Ṣàṣà èèyàn ló le mọ̀dí àṣàmọ̀
Nípa Òǹkọ̀wé:
Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.
Àwòrán Ojú Ìwé Yìí Jẹ́ Ti Culture Trip.
Comments