Àyàjọ́ Falẹ!
À ń gbòròmọdiẹ lọ́wọ́ ikú Tonídìí ní í dà nígbẹ̀yìn bídìí bàjẹ́ Ó tún ti ṣẹ̀ bó ti ń sẹ̀ Ó tún ti bọ̀ bí ìṣe rẹ̀ Emi la fẹ́ sọ fádití ikún ọmọ Péwọ̀n là á jẹ lọ́gẹ̀dẹ̀ tó pọ́n? Kín ló kan lèmọ́mù níbi ajá tó síwín kú? Falẹ! Àlejò tí í wọ̀lú nígbàkan lọ́dún Kó tó dé layé ti ń gbòǹgbẹ rẹ̀ Bó wọ̀lú, á ṣèlú yìndìnyindin Gbogbo aráyé a yófẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn Ọmọ ọ̀ràn tí ń kó póńpó lùyá Falẹ tí ń múnú akọ dùn sábo Gẹ́rẹ́ tó bá wọ̀lú, ìlú á dùn Bó bá kẹ́rù, tó lọ tán Ìlú á bẹ̀rẹ̀ ìrònú tí ò wínrìn Ǹjẹ́ kín ló pàdí ìrònú? Kín ló mómilẹgbẹ ọ̀dọ́bìnrin ń ronú? Èéṣe tádélébọ̀ fi í ṣẹ́tọ́ lẹ́nu bí ìgbín? Akọ ń ronú lórí ohun tí ò ṣe é fọ̀ Falẹ! Àyájọ́ tákọ ń fabẹ́rẹ́ gẹ́lẹ̀ Ọjọ́ tábo ń tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ fákọ́ tẹ̀ Álọ́ọ́mù tán nílé òǹtà Wọ́n fọjú-òpó tó pẹ́ tó ti ṣítè kalẹ̀ Wọn á wá ṣeré délé akọ́ aláìgbọ́n Ìyàwó ń bẹ nílé tó ń sunkún òtútù Ọkọ ń bẹ lọ́ọ̀dẹ̀ tó ń ṣòjòjò àìrígùn Aya yún tán, ó ń sún mọ́kọ Ó fẹ́ gbọ́mọ Ọbà fỌ́ṣun kọ́un? Ẹ ṣọ́ra! Ẹ wòye ohun falẹtáìn kó sínú wọ̀lú Kẹ tó ṣàrìnkò àlejò gogoro Tí n donílé sírònú bó jáde nílùú.
Nípa Òǹkọ̀wé:
Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó, ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yoòbá.
Àwòràn ojú ìwé yìí jẹ́ ti Guardians image:https://cdn.vanguardngr.com/wp-content/uploads/2011/07/sex.jpg
Eléèyíì dára gáàn ni. Káre, akéwì ologbón