Ìpè yìí wà fún àwọn òǹkọ̀wé láti fi ìṣẹ́ wọn ránṣẹ́ sí wa ní Àtẹ́lẹwọ. Iṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìtàn orílẹ̀, ìṣẹ̀dálẹ̀ tàbí ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá. Ó tún le dá lórí àwọn ǹkan alárà-ǹ-barà tó jẹ́mọ àṣà àti ìtàn Yorùbá. Bí àpẹrẹ: Odò Ọ̀ṣun, Òkè Àsabàrí, Òdò Ìyàké, ìtàn ìbejì ní Ìlú Igbó Ọrà abbl. Fún àpẹẹrẹ, ẹni tí ó wá láti Ìbàdàn lè kọ nípa Ìbàdàn (àwọn ǹǹkan tí a lè mọ nípa ìṣẹ̀dálè Ìbàdàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ).

Àwọn ìlànà rè é:

  • Iṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìtàn orílẹ̀, ìṣẹ̀dálẹ̀ tàbí ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá. Ó tún le dá lórí àwọn ǹkan alárà-ǹ-barà tó jẹ́mọ àṣà àti ìtàn Yorùbá. Bí àpẹrẹ: Odò Ọ̀ṣun, Òkè Àsabàrí, Òdò Ìyàké, ìtàn ìbejì ní Ìlú Igbó Ọrà abbl.
  • Ẹ lè fi iṣẹ́ yín ránṣẹ́ ni fidio, eré oníṣe, ìtàn àròkọ, àwòrán, ìfọ̀rọ̀jomitoroọ̀rọ̀, ohùn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
  • Iṣẹ́ náà yóò jáde ní orí àpèèré Àtẹ́lẹwọ́.
  • Ẹ fi iṣẹ́ yín sọwọ́ síwa ní atelewo.org@gmail.com.
  • A ó fún olùkópa kọ̀ọ̀kan ni ẹgbẹ̀rún márùn-ún Naira fun iṣẹ́ wọn
  • Òǹkọ̀wé kan le fi iṣẹ́ tó ju ẹyọkan ránṣẹ́, ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀rún márùn-ún kan náà ni a máa san fún Òǹkọ̀wé kan
  • Òǹkà ọ̀rọ̀ ìfirańṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ wà láàrin ẹgbẹ̀rún kan abọ̀ ọ̀rọ̀ sí ẹgbẹ̀rún marùn-ún ọ̀rọ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Iṣẹ́ náà gbọdọ̀ wà ni inú ẹ̀dà Microsoft Word, ojú ọ̀rọ̀ 12, alálàfo kan ṣoṣo.
  • A ó dẹ́kun ìgbàwọlẹ́ ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹrin ọdún 2023.

Fún aláyè síwájú si nípa ohun k’ohun tí ó ní ṣe pẹ̀lú Àtẹ́lẹwọ́, ẹ kàn sí wa ni +2348188222304 or +2347061282516.

Project Ògùsọ̀: Call for Submission

This is to invite Yorùbá writers to send their creative works to us at Àtẹ́lẹwọ́ for publication. These submissions must engage Yorùbá histories, creation stories, origin stories of places and regions in Yorùbá land. It can also be based on special heritage sites or elements like Ọ̀ṣun river, Àsabàrí Hill, Ìyàké Lake, Igbó Ọrà Twin stories and so on. For example, someone who is a native of Ìbàdàn can write about Ibadan and send to us. You can follow these guidelines:

  • Your work must engage engage Yorùbá histories, creation stories, origin stories of places and regions in Yorùbá land. It can also be based on special heritage sites or elements like Ọ̀ṣun river, Àsabàrí Hill, Ìyàké Lake, Igbó Ọrà Twin stories and so on.
  • You can send your work to us as essay, short story, video, audio, play, interview etc.
  • Your work will be published on our site at www.atelewo.org
  • We will pay a stipend of N5,000 to each contributor whose works are selected from the pool of submissions.
  • A contributor can make multiple submissions, however if we select more than one of such works, we will only pay N5,000 irrespective of the number of works selected from one contributor.
  • Writers are required to send in their works–around 1,500 to 5,000 words or more (1.0 spacing, font size 12)– in a Microsoft Word document format ONLY.
  • You can send your work to atelewo.org@gmail.com
  • The deadline for submissions is April 10, 2023.

For enquiries contact +2348188222304 or +2347061282516.