RASAQ MALIK
Rasaq Malik jẹ́ akẹ́ẹ̀kọ́ gboyè nínú ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ní Ilé Ìwé gíga fásitì èyí tí o fì’dí ka’lẹ̀ sí ìlú Ìbàdàn. O jẹ́ ẹnìkan tí o fẹ́ràn èdè abínibí rẹ̀ púpọ̀púpọ̀. Ní ìgbà tí o wà ní ilé ìwé girama, o jẹ́ ọmọ kan tí ó fẹ́ràn lati maa ka ìtàn àrokọ, àtipé nígbà tí à ń wí yìí ni o ṣalápàde “Egún Aláre” lati ọwọ́ Lawuyì Ògúnniran, “Àìsàn Ìfẹ́” láti ọwọ Bánjọ Akínlabí, “Gbogbo wa lolè”, “Àṣírí Amókùnjalè tú”, “Ọgbọ́n Ọlọ́gbọ́n”, àti bẹ́ẹ̀bẹ lọ. O sì tún jẹ́ ẹnìkan tí o rí àṣà àti ìṣe Yorùbá ní ohún tí o yẹ kí o ṣe kókó sí wá jú ti àtẹ̀yìnwálọ. Nípa bẹẹ, o rí ẹgbẹ Àtẹ́lẹwọ́ ní ẹgbẹ kan ti yòó ṣe àǹfààní fún t’olóri t’ẹlẹ́mù ni òní ati ní ọjọ iwájú.
Ọ̀RẸ́DỌLÁ IBRAHIM
Ọ̀rẹ́dọlá Ibrahim jẹ́ akẹ́kọ́ gboyè ìmọ̀ òfin láti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ìbàdàn. O jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Òmù-Àrán ní ìpínlẹ Kwara nibi tí o ti ni àǹfàní láti kọ́ púpọ̀ nípa iṣe àti àṣà Yorùbá l’ọ́dọ̀ ìyá bàbá rẹ̀ – Alhaja Mọ́ríamọ̀ Ayélàágbe Ọ̀rẹ́dọlá. Ìlú yìí nàá ni o ti lọ ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama níbi tí ó tún ti ní àǹfàní àti kọ́ nípa ẹ̀kọ́ Yorùbá láti ọ̀dọ̀ àwọn òlùkọni tó dágánjíá tí wọ́n sì tún múnádoko pẹ̀lú. Ó k’ẹ́kọ́ jádé ní ilé ẹ̀kọ́ girama Government Secondary School Òmù-Àrán gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ́ tó yege jù lọ ní èdè Yorùbá. Fún ìgbà dìè, Ibrahim ti ṣe ìwọ̀nba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Oníṣòwò kékeré, o sì tún jẹ́ Akéwì, Òǹkọ̀wé, Oníròyìn àti Òṣèré Akẹ́kọ́ ní èdè gẹ̀ẹ̀sì àti ní èdè Yorùbá. Ibrahim jẹ́ ara àwọn òlùdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́, ilé iṣẹ́ SkillNG àti ìwé ìròyìn orí afẹ́fẹ́ ThePageNg. Ìwé lítírésọ̀ Yoruba tí ó fẹ́ràn jùlọ ni Eégún Aláré láti ọwọ́ Láwuyì Ògúnníran. Ibrahim jẹ́ olùkáràmáisìkí ìmọ̀ àti orúkọ rere, o sì ní’gbàgbọ́ pé àpèrè Àtẹ́lẹwọ́ yío ṣe iṣẹ́ takun takun fún ìràpadà ohun to ti sọnù lọ́wọ́ àwọn ọmọ Yorùbá.
RAHAMAN ABÍỌ́LÁ TOHEEB
A bí Abíọlá ní ọdún dìẹ̀ s’ẹ́yìn ní Ìlú Ìsẹ́yìn, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Abíọ́lá jẹ́ ọmọ kan tí ó já fáfá lati kekeré, àti pé o tún ní’fẹ́ lati maa ka ìwé. Kò sí jẹ́ ìyàlẹ́nu pé o jẹ olóri àwọn àkẹ́ẹ̀kọ́ nígbà tí o wà ní ilé ìwé girama (I.D.G.S) ní Ìlú Ìsẹ́yìn. Abíọ́lá jẹ́ akẹ́ẹ̀kó gboyè nínú ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ní Ilé Ìwé gíga fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ eyi tí o fì’dí ka’lẹ̀ sí Ilé-Ìfẹ̀. Ni ìgbà tí Abíọ́lá wà ní fásitì, o jẹ́ ẹnìkan tí òkìkí rẹ kàn gán-án nípa bí o ṣe ń lo èdè gẹ̀ẹ̀sì àti Yorùbá. Ṣèbí ọmọ tí yóò bá jẹ àṣàmú, láti kékeré ni yóò ti maa jẹ’nu ṣámú-ṣámú. Abíọ́lá tún tẹ̀ sí’wajú, o jẹ́ aṣojú sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní ẹ̀ka èdè gẹ̀ẹ́sì nígbà tí o wà ní fásitì ati ọ̀gá àwọn òǹkọ̀wé bákan naa (ANA) nígbà tí o wà ní fásitì. Abíọ́lá rí ẹgbẹ Àtẹ́lẹwọ́ bi ẹgbẹ́ kan tí yóò ran ìdàgbàsókè èdè Yorùbá lọ́wọ́ ni òní ati ní ọjọ́ iwájú.
OWÓYẸMÍ ỌPẸ́YẸMÍ
A bí omidan Ọpẹ́yẹmí ní agbo ilé Olókùnẹṣin ní Ìlú Ọ̀yọ ní ọdún dìẹ̀ sẹ́yìn. Ọpẹ́yẹmí jẹ́ ọmọ tí o mọ ọwọ́ wẹ̀, àtipé kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé omidan yìí jẹ́ akéèkọ́ gboyè nínú èdè abínibí wa ní Òndó, ní fásitì tí o wà lábẹ́ àṣíá fásitì tó gbajúgbajà – Fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀. Àwọn Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “bí irọ́ bá ṣe bi eré lọ bí ẹṣin, irọ́ ni, ọjọ́ kan lòtítọ́ yóò ba”. Àsìkò tó báyìí tí òtítọ́ bá àṣà Yorùbá to fẹ́ lọ sí oko ìpàrun, ìgbìyànjú ÀTẸ́LẸWỌ́ lórí Àṣà Yorùbá kò bíntín, ẹgbẹ́ to mọ̀nà tó sì ní àfojúsùn ni. Omidan yìí gbàwá ni’mọràn pe ki a má ṣe fi pọ̀sì ọ̀làjú sin ogún nla baba wa, àti pé àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀’yà, àjèjì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù d’orí, igi kan ò sì le dá’gbo ṣe.